orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Míkáyà Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Áhábù

1. Fún ọdún mẹ́ta kò sì sí ogun láàrin Árámù àti Ísírẹ́lì.

2. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹ́ta, Jèhósáfátì ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Ísírẹ́lì.

3. Ọba Ísírẹ́lì sì ti wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ti wa ni Ramoti Gílíádì, àwa sì dákẹ́ síbẹ̀, a kò sì gbà á padà lọ́wọ́ ọba Árámù?”

4. Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jèhósáfátì pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti-Gílíádì jà?”Jèhóṣáfátì sì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

5. Ṣùgbọ́n Jèhósáfátì sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

6. Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, bí irinwó (400) ọkùnrin. Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé kí n lọ sí Ramoti-Gílíádì lọ jagun, tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ̀?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

7. Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì béèrè pé, “Ǹjẹ́ wòlíì Olúwa kan kò sí níhìn ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

8. Ọba Ísírẹ́lì dá Jèhóṣáfátì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan sì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Míkáyà ọmọ Ímílà ni.”Jéhósáfátì sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

9. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì sì pe ìránṣẹ́ kan, ó sì wí pé, “Lọ yára mú Míkáyà, ọmọ Ímílà wá.”

10. Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

11. Ṣedekíà ọmọ Kénáánà sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Árámù títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ ”

12. Gbogbo àwọn wòlíì tó kù sì ń sọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà wí pé, “Kọlu Ramoti-Gílíádì, kí o sì ṣẹ́gun.” Wọ́n sì wí pé, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

13. Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Míkáyà wí fún un pé, “Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere.”

14. Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pé, “Bí Olúwa ti wà, ohun tí Olúwa bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un.”

15. Nígbà tí ó sì dé, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Míkáyà, ṣé kí a lọ bá Ramoti-Gílíádì jagun, tàbí kí a jọ̀wọ́ rẹ̀?”Ó sì dáhùn wí pé, “Lọ, kí o sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

16. Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi yóò fi ọ bú pé kí o má ṣe sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”

17. Míkáyà sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì túkáàkiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”

18. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò fọ ire kan sí mi rí bí kò ṣe ibi?”

19. Míkáyà sì tún wí pé, “Nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ogun ọ̀run dúró ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì rẹ̀.

20. Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù láti kọlu Ramoti-Gílíádì? Kí ó sì tọ ikú rẹ̀ lọ níbẹ̀?’“Ẹnìkan wí báyìí, ẹlòmíràn sì sọ mìíràn.

21. Ẹ̀mí kan sì jáde wá, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’

22. “Olúwa sì béèrè pé, ‘Báwo?’ Ó sì wí pé,“ ‘Èmi yóò jáde lọ, èmi yóò sì di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ̀.’“Olúwa sì wí pé, ‘Ìwọ yóò tàn án, ìwọ yóò sì borí, jáde lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’

23. “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ wọ̀nyí. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”

24. Nígbà náà ni Ṣedekíàh ọmọ Kénáánà sì dìde, ó sì gbá Míkáyàh lójú, ó sì wí pé, “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Olúwa gbà lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?”

25. Míkáyà sì wí pé, “Ìwọ yóò rí i ní ọjọ́ náà, nígbà tí ìwọ yóò lọ láti inú ìyẹ̀wù dé ìyẹ̀wù láti fi ara rẹ pamọ́.”

26. Ọba Ísírẹ́lì sì pàṣẹ pé, “Ẹ mú Míkáyà, kí ẹ sì mú un padà sọ́dọ̀ Ámónì, olórí ìlú, àti sọ́dọ̀ Jóásì ọmọ ọba

27. kí ẹ sì wí pé, ‘Báyìí ni ọba wí: Ẹ fi eléyìí sínú túbú, kí ẹ sì fi oúnjẹ ìpọ́njú àti omi ìpọ́njú bọ́ ọ, títí èmi yóò fi padà bọ̀ ní àlàáfíà.’ ”

28. Míkáyà sì wí pé, “Bí ìwọ bá padà bọ̀ ní àlàáfíà, Olúwa kò ti ipa mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún wí pé, “Ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo!”

A Pa Áhábù Ní Ramoti-Gílíádì

29. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhósáfátì ọba Júdà gòkè lọ sí Ramoti-Gílíádì.

30. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún Jèhósáfátì pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

31. Ọba Árámù ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n wí pé, “Ẹ má ṣe bá ẹnìkankan jà, ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, bí kò ṣe ọba Ísírẹ́lì nìkan.”

32. Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jèhósáfátì, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Ísírẹ́lì ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ì yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhósáfátì sì kígbe sókè,

33. àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì padà kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

34. Ṣùgbọ́n ẹnìkan sì fa ọrun rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì ta ọba Ísírẹ́lì láàrin ìpàdé ẹ̀wù irin. Ọba Ísírẹ́lì sì wí fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ dà, kí o sì mú mi jáde kúrò nínú ogun. Èmi ti gbọgbẹ́.”

35. Ogun náà sì le ní ọjọ́ náà, a sì dá ọba dúró nínú kẹ̀kẹ́ kọjú sí àwọn ará Árámù. Ẹ̀jẹ̀ sì sàn jáde láti inú ọgbẹ́ rẹ̀ sí àárin kẹ̀kẹ́ náà, ó sì kú ní àṣálẹ́.

36. A sì kéde la ibùdó já ní àkókò ìwọ̀ oòrùn wí pé, “Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀!”

37. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kú, a sì gbé e wá sí Samáríà, wọ́n sì sin ín ní Samáríà.

38. Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samáríà, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rè, àwọn àgbérè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ.

39. Níti ìyókù ìṣe Áhábù, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ilé eyin-erin tí ó kọ́, àti gbogbo ìlú tí ó tẹ̀dó, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

40. Áhábù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Jèhósáfátì Ọba Júdà

41. Jèhósáfátì ọmọ Áṣà, sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba lórí Júdà ní ọdún kẹrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì.

42. Jèhósáfátì sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba ní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọbìnrin Sílíhì.

43. Ó sì rìn nínú gbogbo ọ̀nà Áṣà baba rẹ̀, kò sì yípadà kúrò nínú rẹ̀; ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa. Kìkì àwọn ibi gíga ni a kò mú kúrò, àwọn ènìyàn sì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí níbẹ̀.

44. Jèhósáfátì sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Ísírẹ́lì.

45. Níti ìyókù ìṣe Jèhósáfátì àti ìṣe agbára rẹ̀ tí ó ṣe, àti bí ó ti jagun sí, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà?

46. Ó pa ìyókù àwọn tí ń hùwà panṣágà ní ọjọ́ Áṣà bàbá rẹ̀ run kúrò ní ilẹ̀ náà.

47. Nígbà náà kò sí ọba ní Édómù; adelé kan ni ọba.

48. Jèhósáfátì kan ọkọ̀ Táríṣíṣì láti lọ sí Ófírì fún wúrà, ṣùgbọ́n wọn kò lọ: nítorí àwọn ọkọ̀ náà fọ́ ní Ésíónì-Gébérì.

49. Ní ìgbà náà Áhásáyà ọmọ Áhábù wí fún Jáhósáfátì pé, “Jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú ọkọ̀,” ṣùgbọ́n Jèhósáfátì kọ̀.

50. Nígbà náà ni Jèhósáfátì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dáfídì, baba rẹ. Jéhórámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Áhásáyà Ọba Ísírẹ́lì

51. Áhásáyà ọmọ Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kẹtàdínlógún Jèhósáfátì ọba Júdà, ó sì jọba ní ọdún méjì lórí Ísírẹ́lì.

52. Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, nítorí tí ó rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀, àti ní ọ̀nà ìyá rẹ̀, àti ní ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó mú Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀.

53. Ó sì sin Báálì, ó sì ń bọ Báálì, ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ ti ṣe.