orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Sólómónì Kọ́ Ilé Náà

1. Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún l (488) ẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọdún kẹrin ìjọba Sólómónì lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.

2. Ilé náà tí Sólómónì ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.

3. Ìloro níwájú tẹ́ḿpìlì ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà.

4. Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà.

5. Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹ́ḿpìlì àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká.

6. Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ìbú, ti àárin sì jẹ́ ìgbọ̀wọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ́ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà.

7. Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú-un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

8. Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìṣàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúṣù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárin, àti láti yàrá àárin bọ́ sínú ẹ̀kẹ́ta.

9. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó Kédárì.

10. Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ìkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi Kédárì.

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sólómónì wá wí pé:

12. “Níti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dáfídì baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀.

13. Èmi yóò sì máa gbé àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi kì ó sì kọ Ísírẹ́lì ènìyàn mi.”

14. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀.

15. Ó sì fi pákó Kédárì tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó fírì tẹ́ ilẹ̀ ilé náà.

16. Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ.

17. Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́.

18. Inú ilé náà sì jẹ́ Kédárì, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìtàkùn àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ Kédárì; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

19. Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí májẹ̀mú Olúwa ka ibẹ̀.

20. Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀.

21. Sólómónì sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó.

22. Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

23. Ní inú-ibi-mímọ́ jùlọ ni ó fi igi ólífì ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga.

24. Apá kérúbù kìn-ní-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì.

25. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèje jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà.

26. Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.

27. Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́-apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrin yàrá náà.

28. Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29. Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù síi àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko.

30. Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31. Nítorí ojú ọ̀nà ibi-mímọ́-jùlọ ni ó ṣe ilẹ̀kùn igi ólífì sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri.

32. Àti lára ilẹ̀kùn igi ólífì náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ.

33. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi ólífì onígun mẹ́rin fún ilẹ̀kùn ilé náà.

34. Ó sì tún fi igi fírì ṣe ilẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀.

35. Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36. Ó sì fi ẹṣẹṣẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹṣẹ kan ìtí kédárì kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37. Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sífì.

38. Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Búlù, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.