orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ayaba Ṣébà Bẹ Sólómónì Wò

1. Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ òkìkí Sólómónì àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ níti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle.

2. Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.

3. Sólómónì sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un.

4. Nígbà tí ayaba Ṣébà sì rí gbogbo ọgbọ́n Sólómónì àti ààfin tí ó ti kọ́.

5. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

6. Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀ èdè mi níti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ.

7. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́.

8. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

9. Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Ísírẹ́lì títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”

10. Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà (120) talẹ́ńtì wúrà, tùràrí olóòórún dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dà bí irú èyí tí ayaba Ṣébà fi fún Sólómónì ọba.

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hírámù tí ó mú wúrà láti ófírì wá wọ́n mú igi Álúgúmù, ógì Sáńdálì lọ́pọ̀lọpọ̀ àti òkúta oníyebíye láti ófírì wá.

12. Ọba sì fi igi Álúgúmù náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin mìíràn fún àwọn akọrin. Irú igi Álúgúmù bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.

13. Sólómónì ọba sì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Sólómónì ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Sólómónì

14. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó lé mẹ́fà talẹ́ńtì wúrà,

15. Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.

16. Sólómónì ọba sì ṣe igba (200) aṣà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan.

17. Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún (300) aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì.

18. Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ èyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó.

19. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, èyín rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni irọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn.

20. Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ọ̀kọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.

21. Gbogbo ohun èlò mímu Sólómónì ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lébánónì sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí ìkankan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkankan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.

22. Ọba sì ní ọkọ̀ Tásísì kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hírámù ní òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tásísì ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín-erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá.

23. Sólómónì ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.

24. Gbogbo ayé sì ń wá ojú Sólómónì láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn.

25. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbááka.

26. Sólómónì sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní egbèje (1400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàata (13,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.

27. Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù bí òkúta, àti igi kédárì ni ó ṣe kí ó dàbí igi síkámórè tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.

28. A sì mú ẹṣin wá fún Sólómónì láti Éjíbítì ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, oníṣòwò ọba ni ó ń mú wọn wá fún òwe.

29. Wọ́n ń mú kẹ̀kẹ́ kan gòkè láti Éjíbítì wá fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹsin kan fún àádọ́jọ (150). Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mú wọn wá fún ọba àwọn ọmọ Hítì àti ọba àwọn ọmọ Árámánì.