orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbé Ayé Jóòbù

1. Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Húsì, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jóòbù; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú,

2. A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un.

3. Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ìbákasíẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọdámàlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀ jù gbogbo àwọn ará ìlà òòrun lọ.

4. Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn.

5. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àṣè wọn pé yíká, ni Jóòbù ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jóòbù wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọkàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jóòbù máa ń ṣe nígbà gbogbo.

Ìdánwò Jóòbù Àkọ́kọ́

6. Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn.

7. Olúwa sì bi Sàtanì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”Nígbà náà ní Sàtanì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọ-siwá-sẹ́yìn lórí ilẹ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

8. Olúwa sì sọ fún Sàtanì pé ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kóríra ìwà búburú.

9. Nígbà náà ni sátanì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jóòbù ha bẹ̀rù Olúwa ní asán bí?

10. Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùṣí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ si ní ilẹ̀.

11. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ”

12. Olúwa sì dá Sàtanì lóhùn wí pé, “Kíyèsí i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”Bẹ́ẹ̀ ni Sàtanì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.

13. Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin:

14. Onísẹ́ kan sì tọ Jóòbù wá wí pé: “Àwọn ọ̀dà-màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn;

15. Àwọn ará Sábà sì kọ lù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”

16. Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lu tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi níkàn ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”

17. Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kádéà píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọ lù àwọn ìbákasíẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lupẹ̀lu wọ́n sì fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”

18. Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnikàn dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n.

19. Sì kíyèsí i, ẹfúfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọdọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.

20. Nígbà náà ni Jóòbù dìde, ó sì fa aṣọ ìgunwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà

21. wí pé:“Ní ìhòòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,ni ìhòòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ síbẹ̀. Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”

22. Nínú gbogbo èyí Jóòbù kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.