orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jóòbù Dá Sófárì Lóhùn

1. Jóòbù wá dahùn, ó sì wí pé:

2. “Ẹ tẹ́tí silẹ̀ dẹdẹ sì àwọn ọ̀rẹ́ mi,kí èyí kí ó jásí ìtùnú tí ó fún mi.

3. Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbàtí mo bá sọ tán, ìwọ máa fi ṣẹ̀sín ń ṣo.

4. “Bí ó ṣe tí èmi ni, àròyé mi iṣe sí ènìyàn bí?Tàbí èétíṣe tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?

5. Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.

6. Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,ìwárìrì sì mú mi lára.

7. Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà níayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?

8. Irú ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojúwọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ-ọmọ wọn ní ojú wọn.

9. Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn.

10. Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísìíṣe; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;

11. Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọnwẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri.

12. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àtiháápù, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè

13. Wọ́n ní ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọnsì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

14. Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fúnỌlọ́run pé, lọ kúrò lọ́dọ̀ wa,nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ!

15. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máasìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

16. Kíyè sí i, àlàáfíà wọn kò sí nípaọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí ni réré.

17. “Ìgbà mélòómélòó ní a ń pa iná ènìyànbúburú kú? Ìgbà mélòómélòó ní ìparunwọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì ímáa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?

18. Wọ́n dàbí àkékù oko níwájúafẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹfúùfù ńlá fẹ́ lọ.

19. Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to iya ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.

20. Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóòsì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.

21. Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilérẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?

22. “Ẹnikẹ́ni le íkọ́ Ọlọ́run ní ìmọ̀?Òun ní í sáa ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.

23. Ẹnìkan a kú nínu pípé agbára rẹ̀,ó wà nínú ìrọra àti ìdákẹ́ pátapáta.

24. Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.

25. Ẹlòmìíràn a sì kú ninú kíkoròọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.

26. Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínúerùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.

27. “Kíyèsí i, èmi mọ̀ ìrò inú yín àtiàrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.

28. Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní iléọmọ aládé, àti níbo ní àgọ́àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’

29. Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjálọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn, pé

30. Ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fúnọjọ́ ìparun? A ó sì mú wọnjáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.

31. Ta ni yóò sọ ipa ọ̀nà rẹ̀ kò ó níojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?

32. Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ósì máa ṣọ́ ibojì òkú.

33. Ògúlùtù àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ ṣíwájú rẹ̀.

34. “Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínúlásán, bí ò ṣepé ní ìdáhùn yín, eké kù níbẹ̀!”