Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àṣè wọn pé yíká, ni Jóòbù ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jóòbù wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọkàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jóòbù máa ń ṣe nígbà gbogbo.