orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọ̀rọ̀ Élífásì: Ọlọ́run Kì í Fi Ìyà Jẹ Olódodo

1. Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà dáhùn wí pé:

2. “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?

3. Kíyèsí i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.

4. Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.

5. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọ lù ọ́;ara rẹ kò lélẹ̀.

6. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹàti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?

7. “Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?

8. Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń se ìtùlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.

9. Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.

10. Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnníunàti eyín àwọn ẹ̀gbọ̀rọ̀ kìnnìún ní a ká.

11. Ógbó kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,àwọn ẹ̀gbọrọ kìnnún sísanra ni a túká kiri.

12. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí a fí ohun lílùmọ́ kan hàn fún mi,etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.

13. Ní ìrò ínú lojú ìrán òru,nígbà tí oorun èjìkà kùn ènìyàn.

14. Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrìtí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.

15. Nígbà náà ni iwin kan kọjá lọ ní iwájú mi,irun ara mi dìde ró ṣánṣán.

16. Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,àwòrán kan hàn níwájú mi,ìdákẹ́ rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:

17. ‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run,ènìyàn kò ha le mọ̀ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?

18. Kíyèsí i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,nínú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀

19. Áńbọ̀ńtórí àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,ẹni tí ìbílẹ̀ wọ́n jẹ́ sí erùpẹ̀tí yóò di rírun kòkòrò.

20. A pa wọ́n run láti òwúrọ̀di alẹ́, wọ́n gbé láé láìrí ẹni kà á sí.

21. A kò ha ké okùn ìye wọ̀n kúrò bí?Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’