orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Senakéríbù Dẹ́rùba Jérúsálẹ́mù

1. Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Heṣekíà ti fi otítọ́ se, Senakéríbù ọba Ásíríà wá ó sì gbógun ti Júdà. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ararẹ̀.

2. Nígbà tí Heṣekáyà rí i pé Senakérébù ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lóri Jérúsálẹ́mù,

3. Ó gbèrò pẹ̀lu àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ tí wọ́n fẹ́rẹ̀ ẹ́ di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

4. Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń ṣàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ naà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Ásíríà fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí.

5. Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ìtorí ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta ìyẹn. Ó sì rán ibi ìfẹ̀yìntì lọ́wọ́ pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé níti ìlú ńlá Dáfídì. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.

6. Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pèwọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

7. “Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má se bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Ásíríà àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ.

8. Agbára ẹran ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, pẹ̀lú wa ni Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekía ọba Júdà wí.

9. Lẹ́yìn ìgbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lákíṣì. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Heṣekáyà ọba Júdà àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí ó wà níbẹ̀:

10. “Èyí ni ohun tí Senakéríbù ọba Ásíríà wí: Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jérúsálẹ́mù lábẹ́ ìgbógun sí?

11. Nígbà tí Heṣekáyà wí pé ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà, ó ń sì yín tọ́ sọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ.’

12. Ṣé Heṣekáyà fún ra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lóri rẹ̀’?

13. “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn bàbá mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi?

14. Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi?

15. Nísinsinyìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà ó tàn yín àti sì yín tọ́ sọ́nà báyìí. Ẹ má se gbàá gbọ́, nítorí tí kò sí Ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn bàbá mi, mélòómélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!”

16. Àwọn ìjòyè Senakéríbù sọ̀rọ̀ ṣíwájú síi ní ìlòdì sí Olúwa Ọlọ́run àti sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Heṣekáyà.

17. Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí: “Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi, Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Heṣekáyà kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi.”

18. Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Hébérù sí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ si wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà.

19. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù bí wọ́n ti ṣe nípa àwọn Ọlọ́run àwọn ènìyàn mìíràn ti àgbáyé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn.

20. Ọba Heṣekáyà àti wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì sunkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí.

21. Olúwa sì ran ańgẹ́lì tí ó pa gbogbo àwọn oko oníjà àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Ásíríà run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.

22. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Heṣekáyà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ Senákéríbù ọba Ásíríà àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà.

23. Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jérúsálẹ́mù fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Heṣekáyà ọba Júdà. Láti ìgbà náà lọ gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ni ó kàá sí.

Ìgbéraga, Àṣeyọrí Àti Ikú Heṣekáyà

24. Ní ọjọ́ wọ̀n nì Heṣekáyà ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa, Tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu.

25. Ṣùgbọ́n ọkàn Heṣekáyà ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara síi inú rere tí a fi hàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lóri Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

26. Nígbà náà Heṣekáyà ronú pìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Heṣekáyà.

27. Heṣekáyà ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, Ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye.

28. Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí titun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àsémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran.

29. Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ iye àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Olúwa ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá.

30. Heṣekíà ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gíhónì. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dáfídì. Ó ṣe àṣeyọrí sí rere nínu gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé.

31. Ṣùgbọ́n nígbà tí ara àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Bábílónì láti bi í lérè nípa àmìn ìyanu tí ó sẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.

32. Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Heṣekíà àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì nínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ìsírẹ́lì

33. Heṣekáyà sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin-ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dáfídì wà. Gbogbo Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Mánásè ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.