orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Hesekíáyà Sọ Ilé Olúwa Di Mímọ́

1. Heṣekáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹẹ̀dọ́gbọ̀n (25) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (25) orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sékáríà.

2. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.

3. Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.

4. Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.

5. Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́.

6. Àwọn baba wa jẹ́ aláìsòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.

7. Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa Fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Ísirẹ́lì.

8. Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìyanu àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.

9. Ìdí nìyí tí àwọn bàbá wa ṣe ṣubú nípa idà àti idí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa ti wọn kó wọ́n ní ìgbékùn.

10. Nísinsìn yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.

11. Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsìn yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”

12. Nígbà náà àwọn ọmọ Léfì wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́:nínú àwọn ọmọ Kóhátì,Máhátì ọmọ Ámásà: àti jóẹ́lì ọmọ Ásáríyà;nínú àwọn ọmọ Mérárì,Kíṣì ọmọ Ábídì àti Ásáríyà ọmọ Jéháiéíèlì;nínú àwọn ọmọ Gésónì,Jóà, ọmọ símà àti Édẹ́nì ọmọ Jóà;

13. nínú àwọn ọmọ Élisáfánì,Ṣímírì àti Jégíèlì;nínú àwọn ọmọ Ásáfù,Sékáríà àti Mátaníyà;

14. nínú àwọn ọmọ Hémánì,Jéhíélì àti Ṣíméhì;nínú àwọn ọmọ Jédútùnì,Ṣémáíà àti Húsíélì.

15. Nigbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ile Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti paáláṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa.

16. Àwọn àlùfaà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa. Àwọn ọmọ Léfì sì mú u wọ́n sì gbé e jáde sí gbangba odò Kédírónì.

17. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyà sí mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní osù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn síi, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fún rarẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹ́rìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.

18. Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Héṣékíà láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò.

19. A ti pèsè àsì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Áhásì ti sọ di aláìmọ́ nínú àìsòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsìn yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.”

20. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hésékíà sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa.

21. Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà. Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ Olúwa.

22. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ: Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.

23. Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn.

24. Àwọn àlùfáà wọn sì pa Òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti pàsẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹṣẹ fún gbogbo Íṣírẹ́lì.

25. Ó sì mú àwọn Léfì dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kíḿbálì ohun èlò orin àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti palásẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Gádì aríran ọba àti Nátanì wòlíì: Èyí ni a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀.

26. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ipè wọn.

27. Hésékíà sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì.

28. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afọ̀npè sì fọn ìpè: gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán.

29. Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbo rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn.

30. Pẹ̀lúpẹ́lú Heṣekáyà ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì, láti fi ọ̀rọ̀ Dáfídì àti ti Ásáfù aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.

Ìrúbọ nínú Tẹ́ḿpìlì.

31. Nígbà náà ni Hesekíáyà dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún Olúwa, ẹ súnmọ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ ọpẹ́ wá sínú ilé Olúwa. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá.

32. Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùnún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn: gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ ṣíṣun sí Olúwa.

33. Àwọn ohun ìyà sí mímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta màlúù, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn.

34. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣe náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Léfì ṣe olóòtọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́.

35. Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun-mímu fún ẹbọ sísun.Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún dá ti iṣẹ́-ìsìn ilé Olúwa sílẹ̀.

36. Heṣekáyà sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà.