orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Júdà, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn òpó Áṣérà lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ Jákè jádò Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ní Éfíráimù àti Mánásè. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.

Ìdáwó Fún Ìjọ́sìn.

2. Heṣekíà fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Léfì láti tẹ́ ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu ọ̀nà ibùgbé Olúwa.

3. Ọba dá láti ara ohun ìni rẹ̀ fun ọrẹ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ọrẹ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti àsè yíyàn gẹ́gẹ́ bi a ti se kọ ọ́ nínú òfin Olúwa.

4. Ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Léfì, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jìn fún òfin Olúwa.

5. Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkóso ti ọkà wọn, ọtí titun òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan.

6. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti Júdà ti gbe inú àwọn ìlú Júdà pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun Ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkítì.

7. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣiṣe èyí ní oṣù kẹ́ta, wọ́n sì parí ní oṣù kéje.

8. Nígbà tí Heṣekáyà àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkítì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.

9. Heṣekáyà bèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì nípa òkìtì;

10. Sádókù sì dáhùn pé “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì sẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”

11. Heṣekáyà pàsẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìpamọ́ nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí.

12. Nígbà náà wọ́n fi tọkàntọkàn mú ìdáwó wọn wá ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn yíyà sọ́tọ̀. Kónánáyà ará Léfì wà ní ìdí nǹkan wọ̀nyí àti arákùnrin rẹ̀ Ṣíméhì jẹ́ àtẹ̀lé e rẹ̀ lóyè.

13. Jéhíélì, Áṣáṣíà, Náhátì, Ásáhélì, Jérímótì, Joábádì, Élíélì, Ísímákíà, Máhátì àti Bénáyà jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konáníà àti Ṣíméhì arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Heṣekáyà àti Áṣáríyà oníṣẹ́ ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.

14. Kórè ọmọ ímínà ará Léfì Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, pí pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀

15. Édẹ́nì, Miníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Ámáríyà àti Ṣekánáyà ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹ́gbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.

16. Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbi ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínu ìtàn ìdíle láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbàwọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn.

17. Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Léfì ogún ọdún tàbí jùbẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpínnu àti ìpín wọn.

18. Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kékèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlu. Tí a kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé yìí ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.

19. Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Árónì, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàárin wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Léfì.

20. Èyí ni Heṣekáyà ṣe jákèjadò Júdà, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀,

21. Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé níti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.