“Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má se bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Ásíríà àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ.