orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jósíà Ṣe Ìrántí Àjọ Ìrékọjá

1. Síwájú síi, Jósíà ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ẹran ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní.

2. Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa.

3. Ó sì wí fún àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí ó sọ fún gbogbo àwọn Ísírẹ́lì ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Sólómónì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsìn yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.

4. Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Sólómónì.

5. “Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Léfì fún ọ̀kọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀.

6. Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹ̀ran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa paláṣẹ láti ọwọ́ Mósè.”

7. Jósíà sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ ẹgbàámẹ́ẹ̀dógún ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọmọ ewurẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n akọ màlúù (3,000) gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba.

8. Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn Àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Hílíkíyà, Sekaríà àti Jéhíélì, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún ẹran ọ̀sìn (300).

9. Àti pẹ̀lú Koníà àti pẹ̀lú Ṣémíà àti Nàtaníẹ́lì, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabíà, Jélíélì àti Joábádì olórí àwọn ọmọ Léfì, ó sì pèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹbọ ìrékọjá (500) àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Léfì.

10. Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á lásẹ.

11. Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Léfì sì bo ẹranko.

12. Wọ́n sì ya àwọn ẹbọ sísún sí apá kan láti fi wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ìdílé àwọn ènìyàn láti rúbọ sí Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọọ́ sínú ìwé Mósè. Wọ́n sì se bákan náà pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn.

13. Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná Gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú odù àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákía fún gbogbo àwọn ènìyàn.

14. Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Árónì, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àsálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Árónì àlùfáà.

15. Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Ásáfù, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dáfídì, Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì àwọn aríran ọba àti àwọn olùsọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ti múra sílẹ̀ fún wọn.

16. Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn Olúwa ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ọba Jósíà ti paá lásẹ.

17. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje.

18. Àjọ ìrékọjá náà kòsì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Ísírẹ́lì títí dé ọjọ́ wòlíì Sámúẹ́lì, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jósíà ti se, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn Júdà àti Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù.

19. Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlogún ìjọba Jósíà

Ikú Jósíà

20. Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Jósíà ti tún ilẹ̀ náà se tán, Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ láti bá Keríkemísì jà lórí odo Éúfírátè, Jósíà sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

21. Ṣùgbọ́n Nékò rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrin èmi àti ìwọ, ọba Júdà? Kìí se ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bàá pa ọ́ run.”

22. Jósíà, bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tí kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le báa jà, kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó lọ láti jà lórí àfonífojì Mégídò.

23. Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Jósíà, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹgbé mi kúrò, èmi sì ti gba ọgbẹ́ gidigidi.”

24. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Júdà àti gbogbo Jérúsálẹ́mù sì sọ̀fọ̀ fún un.

25. Jeremáyà sì pohùn réré ẹkún fún Jósíà, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Jósíà nínú orin ẹkún wọn títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jérúsálẹ́mù, a sì kọọ́ sínú àwọn orin ẹkún.

26. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jósíà àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínu ìwé òfin Olúwa.

27. Gbogbo iṣẹ́ náà, àti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà.