Ìṣe Àwọn Àpósítélì 24:25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Bí Pọ́ọ̀lù sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líkísì, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsìn yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”