orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Bá Ará Bẹ́ńjámínì Jà

1. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Dánì dé Bááṣébà, àti láti ilẹ̀ Gílíádì jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ ṣíwájú Olúwa ni Mísípà.

2. Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì dúró ní ipò wọn ní àpèjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn.

3. (Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù ti gòkè lọ sí Mísípà). Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”

4. Ará Léfì náà, ọkọ obìrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gíbíà lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú.

6. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí-ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbégbé ìní Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

7. Nísinsinyìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

8. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnìkankan nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò se sí Gíbíà ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.

10. A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”

11. Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì para pọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12. Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárin yín?

13. Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì.”Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì.

14. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gíbíà láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.

15. Ní ẹṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ àwọn ará Bẹ́ńjámínì kó ẹgbàá mẹ́talá (26,000) àwọn ọmọ ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gíbíà.

16. Ní àárin àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára débi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàṣé (wọ́n jẹ́ ata má tàṣe).

17. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, yàtọ̀ sí àwọn ará Bẹ́ńjámínì, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Júdà ni yóò kọ́ lọ.”

19. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dóti Gíbíà (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gíbíà).

20. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde lọ láti bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gíbíà.

21. Àwọn ọmo Bẹ́ńjámínì sì jáde láti Gíbíà wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.

23. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ wọ́n sunkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì.

25. Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Bẹ́ńjámínì jáde sí wọn láti Gíbíà, láti dojú kọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

26. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sunkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà (ọrẹ ìrẹ́pọ̀) sí Olúwa.

27. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run wà níbẹ̀,

28. Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

29. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì yàn àwọn ènìyàn tí ó lúgọ (sápamọ́) yí Gíbíà ká.

30. Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gíbíà bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí.

31. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹ́tẹ́lì àti èkejì sí Gíbíà.

32. Nígbà tí àwọn Bẹ́ńjámínì ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”

33. Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Báálì Támárì, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọ́n sápamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀ oòrùn Gíbíà.

34. Nígbà náà ni ẹgbàá márùn ún (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbógun ti Gíbíà láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò funra pé ìparun wà nítòsí.

35. Olúwa ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbàá méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,000) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.

36. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn.Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fà sẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gíbíà.

37. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gíbíà, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà.

38. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti àwọn tí ó lúgọ sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó lúgọ fi ẹ̀ẹ́fín ṣe ìkúukùú ńlá láti inú ìlú náà,

39. nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yípadà, wọ́n sá gun.Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó to ọgbọ̀n (30), wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.”

40. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkúukùú ẹ̀ẹ́fín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì yípadà wọ́n sì rí ẹ̀ẹ́fín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.

41. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu.

42. Wọ́n sì sá níwáju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.

43. Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbégbé ìlà oòrùn Gíbíà.

44. Ẹgbàá mẹ́sàn án (18,000) àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun.

45. Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sá lọ sí apá aṣálẹ̀ lọ sí ọ̀nà àpáta Rímónì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì títí dé Gídómù wọ́n sì tún bi ẹgbàá (2000) ọkùnrin ṣubú.

46. Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Bẹ́ńjámínì tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun.

47. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rámónù, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.

48. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà sí àwọn ìlú Bẹ́ńjámínì wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.