orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jẹ́fítà Àti Éfúráímù

1. Àwọn ọkùnrin Éfúráímù pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí Sáfónì, wọ́n sì bi Jẹ́fítà pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ámónì jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò ṣun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”

2. Jẹ́fítà dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ámórì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn.

3. Nígbà tí mo ríi pé ẹ̀yin kò ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́, mo fi ẹ̀mi mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ámónì jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”

4. Jẹ́fítà sì pe àwọn ọkùnrin Gílíádì, wọ́n sì bá àwọn ará Éfúráímù jà. Àwọn ará Gílíádì run wọ́n nítorí pé àwọn ará Éfúráímù ti ṣọ tẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gílíádì jẹ́ àṣáwọ̀ (ìṣáǹṣá) àwọn ará Éfúráímù àti ti Mànásè.”

5. Àwọn ará Gílíádì gba àbáwọdò Jọ́dánì tí wọ́n máa gbà lọ sí Éfúráímù, nígbàkígbà tí àwọn ará Éfúráímù bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sá lọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gílíádì yóò bi í pé, “Ṣé ará Éfúráímù ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,”

6. wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣhíbólétì.’ ” Tí ó bá ní, “Síbólé,” tì torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáadáa, wọ́n á mú-un wọn, a sì pa á ni àbáwọdò Jọ́dánì. Àwọn ará Éfúráímù tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin.

7. Jẹ́fítà ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jẹ́fítà ará Gílíádì kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gílíádì.

Ìbísánì, Élónì, Ábídónì (Àwọn Onidàájọ́ kékeré)

8. Lẹ́yìn Jẹ́fítà, Íbísánì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

9. Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méje.

10. Lẹ́yìn náà ni Íbísánì kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

11. Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá.

12. Élónì sì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Ṣébúlúnì.

13. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ábídónì ọmọ Hiélì tí Pírátónì n ṣe àkóso Ísírẹ́lì.

14. Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́jọ.

15. Ábídónì ọmọ Híélì sì kú, wọ́n sin ín sí Pírátónì ní ilé Éfúráímù ní ìlú òkè àwọn ará Ámálékì.