orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran túntún ní Ísírẹ́lì wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun, àwọn ará Kénánì.

2. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Ísírẹ́lì tí kò rí ogun rí ní bí a ti ṣe ń jagun):

3. Àwọn ìjòyè ìlú Fílístínì máràrùn, gbogbo àwọn ará Kénánì, àwọn ará Ṣídónì, àti àwọn ará Hífì tí ń gbé ní àwọn òkè Lébálónì bẹ̀rẹ̀ láti òkè Báálì-Aámónì títí dé Lébò Hámátì.

4. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè.

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.

6. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

Ótiníẹ́lì

7. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa. Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.

8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

10. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

11. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Ótíníẹ́lì fi kú.

Éhúdú

12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí. Olúwa fún Égílónì, ọba àwọn Móábù ní agbára ní orí Ísírẹ́lì.

13. Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ ogun Ámálékì ní Égílónì gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ (Jẹ́ríkò).

14. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sin Égílónì ọba Móábù fún ọdún méjìdínlógún

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà sí wọn, Éhúdù ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gérà ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Éhúdù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi owó orí wọn rán sí Égílónì olú ìlú Móábù ní ọdọọdún fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

16. Ṣùgbọ́n kí ó tó lọ ní ọdún yìí Éhúdù ti ṣe idà mímú olójú méjì kan tí gígùn rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ tó ẹṣẹ̀ kan ààbọ̀, ó sì fi pamọ́ sínú àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún.

17. Éhúdù gbé owó orí náà lọ bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ó sì fi fún Égílónì ẹni tí ó sanra púpọ̀.

18. Lẹ́yìn tí ó ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.

19. Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta, òun padà ṣẹ́yìn, ó sì wí fún ọba pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ àsírí láti bá ọ sọ.”Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń sọ sì jáde síta kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

20. Éhúdù lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Éhúdù sì wí fún-un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,

21. Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.

22. Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.

23. Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.

24. Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”

25. Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyànu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì sí ilẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.

26. Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Éhúdù ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Ṣéírà.

27. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó fọn fèrè ní orí òkè Éfúráímù, fèrè ìpè ogun, ó sì kó ogun jọ lábẹ́ ara rẹ̀ bí olórí ogun.

28. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.

29. Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Móábù tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.

30. Ní ọjọ́ náà ni Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Móábù, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.

Ṣáḿgárì

31. Lẹ́yìn Éhúdù, ni ṣáḿgárì ọmọ Ánátì ẹni tí ó pa ọgọ́rùn ún mẹ́fà Fílístínì pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Ísírẹ́lì kúrò nínú ìpọ́njú.