Onídájọ́ 20:26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sunkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà (ọrẹ ìrẹ́pọ̀) sí Olúwa.