orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọrẹ Ẹbọ Sísun

1. Olúwa sì pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé;

2. “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.

3. “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ múu wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó bá à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa

4. kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.

5. Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájù Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í se ọmọ Árónì yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.

6. Òun yóò bó àwọ ara akọ ọ̀dọ́ màlúù náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́.

7. Àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà.

8. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò tò ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí ori igi tó ń jó lórí pẹpẹ.

9. Kí ó fi omi ṣàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

10. “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn agutan tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù,

11. kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká

12. Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.

13. Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa

14. “ ‘Bí ọrẹ tí a fẹ́ fi fún Olúwa bá jẹ́ ti àwọn ẹyẹ, kí ó mú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé

15. Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.

16. Kí ó yọ àjẹsí (àpò oúnjẹ) ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà

17. Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má yaá tan pátapáta. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ọrẹ ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa.