orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ègbé Ni Fún Àwọn Tí Ara Rọ̀

1. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Síónìàti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaríààti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdètí ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì máa ń tọ̀ ọ́ wá

2. Ẹ lọ Kálínì kí ẹ lọ wò óKí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Ámátì ìlú ńlá a nì.Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gátì ní ilẹ̀ FílístínìǸjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ?Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju ti yín lọ bí?

3. Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòòsí

4. Ẹ̀yin sùn lé ibusùn tí a fi eyín erin ṣeẸ sì tan ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùnẸ̀yin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yín jẹẸ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrin agbo wọn jẹ

5. Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i DáfídìẸ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ̀ àwọn ohun èlò orin

6. Ẹ̀yín mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kanàti ìkunra tí o dára jùlọṢùgbọ́n ẹ̀yin kò káànú ilé Jósẹ́fù tí o di ahoro

7. Nitorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùnpẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùnàwẹ̀jẹwẹ̀mú àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò

Olúwa Kórìíra Ìgbéraga Ọmọ Ísírẹ́lì

8. Olúwa ọ̀gá ògo ti búra fúnra rẹ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára sì ti wí pé:“Mo kórìíra ìgbéraga Jákọ́bùn kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”

9. Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá sẹkù nínú ile kan, àwọn náà yóò kú

10. Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béérè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó farapamọ́ níbẹ̀, “Njẹ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”

11. Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,Oun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúúÀti sísán kọlu ilé kékèké.

12. Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi ẹṣin kọ́ ni lórí àpáta bí?Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí ọ̀títọ́ padà sí májèléẸ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.

13. Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí LódábárìẸ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í se agbára wa ni àwa fi gba Kánáímù?”

14. Nítorí Olúwa Ọlọ́run alágbára wí pé,“Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Ísírẹ́lì,tí yóò máa ni ọ́ lára ní gbogbo ọ̀nàláti ẹnu ọ̀nà ìwọlé Hámátì títí dé àfonífojì aginjù.”