orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì, ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn Tékóà; ohun tí o rí nípa Ísírẹ́lì ní ọdun méjì ṣáàjú ilẹ̀ riri, nígbà tí Úsáyà ọba Júdà àti Jéróbóámù ọmọ Jéóhásì jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

2. Ó wí pé:“Olúwa yóò bú jáde láti Síóníohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jérúsálẹ́mù wá;Ibùgbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,Orí-òkè Kámẹ́lì yóò sì rọ.”

Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Ísírẹ́lì

3. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Dámásíkù,àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padaNítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gílíádì.Pẹ̀lú ohun èlo irin tí ó ní eyín mímú

4. Èmi yóò rán iná sí ilé HásáélìÈyí ti yóò jó àwọn ààfin Bẹni-Hádádì run.

5. Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdáàbú Dámásíkù;Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áfénì runÀti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Bẹti-Édénì.Àwọn ará a Árámù yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kírì,”ni Olúwa wí.

6. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gásà,àní nítorí mẹ́rin,Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padàGẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbékùn.Ó sì tà wọ́n fún Édómù,

7. Èmi yóò rán iná sí ara odi Gásàtí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run

8. Èmi yóò ké àwọn olùgbé Ásódì kúrò.Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Ákélónì mú.Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ékírónìtítí tí ìyókù Fílístínì yóò fi ṣègbé,”ni Olúwa Ọlọ́run wí.

9. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tírèàní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbékùn fún ÉdómùWọn kò sì nán-án-ní májẹ̀mú ọbàkan,

10. Èmi yóò rán iná sí ara odi TírèTí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”

11. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Édómù,àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padàNítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,Ó sì gbé gbogbo àánú sọnùìbínú rẹ̀ sì ń faniya títíó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́

12. Èmi yóò rán iná sí orí TémánìTí yóò jó gbogbo ààfin Bósírà run.”

13. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ámónìàní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gílíádìkí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.

14. Èmi yóò rán iná sí ara odi RábàÈyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ runpẹ̀lú igbe ní ọjọ́ ogunpẹ̀lú ìjì ní ọjọ́ ààjà

15. Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùnÒun àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ lápapọ̀,”ni Olúwa wí.