orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Eṣú, Iná Àti Ìwọ̀n Okùn

1. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mí: Ó pèsè ọwọ́ esú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀.

2. Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ọ́, dáríjìn! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

3. Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí;“Èyí kò ni sẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.

4. Èyí ni ohun ti Olúwa Ọlọ́run fi hàn mí: Olúwa Ọlọ́run ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.

5. Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Ọlọ́run jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

6. Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa alágbára wí

7. Èyí ni ohun tí ó fi hàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn-ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀.

8. Olúwa sì bi mi pé, “Ámósì, kí ni ìwọ rí?”Mo dáhùn pé, “Okùn-ìwọ̀n.”Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wòó, Èmí ń gbé okùn-ìwọ̀n kalẹ láàárin àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́

9. “Ibi gíga Ísáákì wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoroàti ibi mímọ Ísírẹ́lì wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.Èmi yóò sì fi idà dide sí ilé Jéróbóámù.”

Ámósì àti Ámásáyà

10. Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé: “Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.

11. Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ:“ ‘Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú,Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn,jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

12. Nígbà náà ni Ámásáyà sọ fún Ámósì pé “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Júdà. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀ ki o sì sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.

13. Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Bẹ́tẹ́lì nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹ́ḿpìlì ìjọba rẹ̀.”

14. Ámósì dá Ámásáyà lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùsọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.

15. Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́tẹ̀ fun àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

16. Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,“ ‘Má ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí Ísírẹ́lìMá ṣì ṣe wàásù sí ilé Ísáákì.’

17. “Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di paṣángà ni ìlú,àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.A ó wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín inàti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.Ísírẹ́lì yóò sì lọ sí ìgbèkùn,kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”