orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ẹ̀rí Jíjẹ́ Nípa Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Éjíbítì:

2. “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yànnínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ níyàfún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

3. Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀láìjẹ́ pé wọ́n ti gbà láti ṣe é?

4. Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbo,bí kò bá ní ohun ọdẹ?Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀bí kò bá rí ohun kan mú?

5. Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?

6. Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?Tí ewu bá wú ìlúkò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?

7. Nítòótọ́ Olúwa Ọlọ́run kò ṣe ohun kanláìfi èrò rẹ̀ hànsí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

8. Kìnnìún ti bú ramúramùta ni kì yóò bẹ̀rù? Olúwa Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ta ni le ṣe àìsọtẹ́lẹ̀?

9. Ẹ kéde ní ààfin Áṣídódùàti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì.“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samáríà;Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrin rẹ̀àti ìnílára láàrin àwọn ènìyàn rẹ.”

10. “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,“Ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”

11. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;yóò wó ibi gíga yín palẹ̀a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

12. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjìkúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kanbẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,tí ń gbé Samáríà kúròní igun ibùsùn wọnní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”

13. “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run alágbára.

14. “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run;ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúròyóò sì wó lulẹ̀.”

15. “Èmi yóò wó ilé òtútùlulẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀ẹ̀rùn;ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbéa ó sì pa ilé ńlá náà run,”ni Olúwa wí.