orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Olúwa wí;“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Móábù,àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,Nítorí ó ti sun-ún, di eérú,egungun ọba Édómù

2. Èmi yóò rán iná sí orí MóábùÈyí tí yóò jó àwọn ààfin Kéríótì run.Móábù yóò sì kú pẹ̀lú ariwopẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè

3. Èmi yóò ké onídájọ́ rẹ̀ kúròÈmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”ni Olúwa wí;

4. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Júdà,àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padàNítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nàÒrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé

5. Èmi yóò rán iná sí orí JúdàÈyí tí yóò jó àwọn ààfin Jérúsálẹ́mù run.”

Ìdájọ́ tí Yóò Wá Sórí Ísírẹ́lì

6. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Ísírẹ́lìàní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padàwọ́n ta olódodo fún fàdákààti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.

7. Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn talákà mọ́lẹ̀bí wọ́n ti ń tẹ ẹrùpẹ̀ ilẹ̀tí wọ́n sì fi òtítọ́ du àwọn tí a ni láraBaba àti ọmọ ń wọlé tọ wúndíá kan náàLáti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́

8. Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bá a pẹpẹLórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ní ilé òrìṣà wọnwọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtanràn.

9. “Mo pa àwọn ará Ámórì run níwájú wọngíga ẹni tí ó dàbí igi Kédárì.Òun sì le koko bí igi Óákùmo pa èso rẹ̀ run láti òkè wáàti egbò rẹ̀ láti ìṣàlẹ̀ wá.

10. “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá,mo sì sìn yín la ihà já ní ogójì ọdúnláti fi ilẹ̀ àwọn ará Ámórì fún un yín.

11. Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàárin àwọn ọmọ yínàti láàárin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Násárátìèyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Ísírẹ́lì?”ni Olúwa wí.

12. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Násárátì ní ọtí muẸ sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

13. “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.

14. Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọalágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

15. tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣinkì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

16. àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọyóò sálọ ní ìhòòhò ní ọjọ́ náà,”ni Olúwa wí.