orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Agbọ̀n Èso Pípọ́n

1. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n.

2. Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.”Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

3. Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹ́ḿpìlì yóò yí padà sí ohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú-ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

4. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,tí ẹ sì ń sọ talákà di ilẹ

5. Tí ẹ ń wí pé,“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò paríkí àwa bá à lè ta ọkàkí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópinkí àwa bá à le ta jéró?”Kí a sì dín ìwọ̀n wa kùkí a gbéraga lórí iye tí a ó tà ákí a sì fi òṣùnwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ

6. Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn talákàkí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìníkí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀

7. Olúwa ti fi ìgbéraga Jákọ́bù búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọkan nínú ohun tí wọ́n ṣe.

8. “Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha sọ̀fọ̀?Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Náílì,yóò sì ru ú sókè pátapáta bí ìkún omia ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Éjíbítì.

9. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Ọlọ́run wí,“Èmi yóò mú òòrùn wọ̀ ní ọ̀sán,Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀ṣán gangan.

10. Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀,gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún.Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀,kí a sì fá orí i yín.Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrinkan ṣoṣo tí a bí àti opin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

11. “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Ọlọ́run wí,“nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òùngbẹ fún omi.Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

12. Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti òkun dé òkunwọn yóò sì máa rìn ká láti gúṣù sí àríwá,wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwaṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

13. “Ní ọjọ́ náà“àwọn arẹwà wúndíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrinyóò dákú fún òùngbẹ omi.

14. Àwọn tí ó fi òrìṣà Samaríà búra tí wọ́n wí pé,‘tí wọ́n sì wí pé, ìwọ Dánì, ọlọ́run rẹ ń bẹ láàyè,’àti bi ó ti dájú pé ọlọ́run Báṣébà ti ń bẹ láàyèàní, wọn yóò ṣubú, wọn kì yóò sì tún dìde mọ́.’ láàyè ìwọ Dánì.’Bí ó ti dájú pè ọlọrun rẹ ń bẹ láàyè ìwọ BáṣébàWọ́n yóò ṣubú,Wọn kì yóò si tún díde mọ.”