orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Wò Mí Kí O Sì Yè

1. Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:

2. “Wúndíá Ísírẹ́lì ṣubúláì kò sì le padà dìdeó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀kò sí ẹni tí yóò gbé e nàró.”

3. Èyí ni ohun tí Olúwa ọ̀gá ògo wí:“Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde,yóò dín ku ọgọ́run ní Ísírẹ́lì.Ìlú tí ọgọ́run alàgbà ti jádeyóò ṣẹ́ku ẹni mẹ́wàá.”

4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Ísírẹ́lì:“Wá mi kí o sì yè;

5. Ẹ má ṣe wá Bẹ́tẹ́lì,Ẹ má ṣe lọ sí GílígálìẸ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Bíáṣébà.Nítorí dájúdájú a ó kó Gílígálì ní ìgbèkùnA ó sì sọ Bẹ́tẹ́lì di asán.”

6. Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè,Kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Jósẹ́fùA sì jó o runBẹ́tẹ́lì kò sì ní rí ẹni tí yóò bomi pa á.

7. Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkoròTí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀

8. Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Píláédì àti ÓríónìẸni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀Tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹẸni tí ó wọ́ omi òkun jọpọ̀Tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

9. Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódiTí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ aládé di ahoro

10. Ìwọ kórìíra ẹni tí ń ṣòdì ní ẹnu ibodèó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́

11. Ìwọ ń tẹ talákà mọ́lẹ̀o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọnNítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́léṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọnNítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn

12. Nítorí mo mọ iye àìṣedédé rẹmo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀o sì ń fi òtítọ́ du talákà ní ilé ẹjọ́

13. Àwọn ọlọgbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyíNítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.

14. Wá rere, má ṣe wá búburúkí ìwọ ba à le yèNígbà náà ni Olúwa alágbára yóò wà pẹ̀lú ù rẹ.Òun yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ bí ìwọ ṣe wí

15. Kòrìírà búburú kí o sì fẹ́ rereDúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́Bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbárayóò síjú àánú wo ọmọ Jósẹ́fù tó ṣẹ́kù

16. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run alágbára wí:“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónàigbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlúA ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sunkúnÀti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún

17. Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàràNítorí èmi yóò la àárin yín kọjá,”ni Olúwa wí.

Ọjọ́ Olúwa

18. Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́nítorí ọjọ́ Olúwakí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́

19. Yóò dàbí ọkùnrin tí ó sá láti ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.Tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu ẹkùnyóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọtí ó simi lé ògiri ilé rẹ̀tí ejò sì bù ú ṣán.

20. Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?Tí ó sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀

21. “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àṣè ẹ̀sìn in yínÈmi kò sì ní inú dídùn sí àpèjọ yín

22. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà wáÈmi kò ní tẹ́wọ́n gbà wọ́nBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.Èmi kò ní náání wọn.

23. Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìnÈmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

24. Jẹ́ kí òtítọ́ ṣàn bí odòàti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ

25. “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wání ogójì ọdún ní ihà ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

26. Ẹ̀yin ń gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yínibùgbé àwọn òrìṣà yínàní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

27. Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Dámásíkù,”ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.