Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 49:3-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,Ísírẹ́lì nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”

4. Ṣùgbọ́n èmi ṣọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀ mófo.Síbẹ̀ síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sími sì wà lọ́wọ́ Olúwa,èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”

5. Nísinsìn yìí Olúwa wí péẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀láti mú Jákọ́bù padà tọ̀ mí wáàti láti kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OlúwaỌlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi

6. Òun wí pé:“Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ miláti mú ẹ̀yà Jákọ́bù padà bọ̀ sípòàti láti mú àwọn ti Ísírẹ́lì tí mo ti pamọ́.Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wásí òpin ilẹ̀ ayé.”

7. Ohun tí Olúwa wí nìyìíOlùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì—sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kóríralọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè,sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:“Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,àwọn ọmọ ọba yóò ríi wọn yóò sì wólẹ̀,nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olótìítọ́,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí ó ti yàn ọ́.”

8. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípòàti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,

9. Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nààti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.

10. Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òrùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí òòrùn kí ó pa wọ́n.Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi oríṣun omi.

11. Èmi yóò sọ gbogbo àwọn oke-ńlá mi di ojú-ọ̀nààti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé ṣókè.

12. Kíyèsí i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jínjìnàwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀láti ìwọ̀ oòrùn,àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Áṣíwánì.”

13. Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run;yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé;bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá!Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínúyóò sì ṣàánú fún àwọn ẹnití a ń pọ́n lójú.

14. Ṣùgbọ́n Ṣíhónì sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.”

15. “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbéÈmi kì yóò gbàgbé rẹ!

16. Kíyèsí i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ miògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.

17. Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.

18. Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká;gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọwọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè,” ni Olúwa wí,“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

19. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahorotí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìgbòrò,ní ìsinsìn yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti ó jẹ ó rùn ni yóòwà ni ọ̀nà jínjìn réré.

20. Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹyóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’

21. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?A fi èmi nìkan sílẹ̀,ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22. Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí níyìí:“Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlàÈmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọnwọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrinní èjìká wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 49