orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jésù Rán Àádọ́rin Ọmọ-Ẹ̀yìn Jáde

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn míràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjìméjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkárarẹ̀ yóò sì dé.

2. Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.

3. Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́ àgùntàn sáàrin ìkookò.

4. Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

5. “Ní ilékílé tí ẹ̀yín bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlààáfíà fún ilé yìí!’

6. Bí ọmọ àlààáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.

7. E dúró sínú ilé yẹn, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fifún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe ṣí láti ilé dé ilé.

8. “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín:

9. Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’

10. Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde sí ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé,

11. ‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù dẹ̀dẹ̀ sí yín!’

12. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sódómù ní ìjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

13. “Ègbé ni fún ìwọ, Kórásínì! Ègbé ni fún ìwọ Bẹtiṣáídà! Nítorí ìbáṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tírè àti Ṣídónì, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú.

14. Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tírè àti Sídónì nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.

15. Àti ìwọ, Kápánáúmù, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

16. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi: ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

17. Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

18. Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.

19. Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

20. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

21. Ní wákàtí kan náà Jésù yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sáà yẹ ní ojú rẹ.

22. “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

23. Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.

24. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

Òwe Aláàánú Ará Samáríà.

25. Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26. Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Bí ìwọ ti kà á?”

27. Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

28. Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere: ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29. Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jésù wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30. Jésù sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.

31. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà: nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì.

32. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì.

33. Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é.

34. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkalárarẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

35. Nígbà tí ó sì lọ ní ijọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Má a tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’

36. “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀èta wọ̀nyí, tani ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37. Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un.”Jésù sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

Ní Ilé Mátà Àti Màríà.

38. Ó sì se, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Mátà sì gbà á sí ilé rẹ̀.

39. Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹṣẹ̀ Jésù, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40. Ṣùgbọ́n Mátà ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkàn ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

41. Ṣùgbọ́n Jésù sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Mátà, Mátà, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.

42. Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Màríà sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”