orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Òwe Àgùntàn Tó Sọnu

1. Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

2. Àti àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

3. Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé,

4. “Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipaṣẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i?

5. Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀.

6. Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’

7. Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòótọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rún-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.

Òwe Owó Tó Sọnù

8. “Tàbí obìnrin wo ni ó ní fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i?

9. Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí fàdákà tí mo ti sọnù.’

10. Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́sẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Òwe Ọmọ Tó Sọnù

11. Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì:

12. “Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

13. “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá.

14. Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní.

15. Ó sì lọ, ó da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ́tọ̀ kan ní ilẹ̀ náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.

16. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ẹnikẹ́ni kò sì fifún un.

17. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mí mélòómélòó ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìnín.

18. Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ bàbá mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Bàbá, èmí ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ;

19. Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’

20. Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ.“Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

21. “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!

22. “Ṣùgbọ́n Baba náà wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀:

23. Ẹ sì mú ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá:

24. Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í se àríyá.

25. “Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin òun ijó.

26. Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kíni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí?

27. Ó sì wí fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlààáfíà àti ní ìlera.’

28. “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; bàbá rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í sìpẹ̀ fún un.

29. Ó sì dáhùn ó wí fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wòó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá:

30. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà ru ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ìwọ sì ti pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa fún un.’

31. “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.

32. Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”