orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pílátù.

2. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó-òde fún Késárì, ó ń wí pé, òun tìkara-òun ni Kírísítì ọba.”

3. Pílátù sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”

4. Pílátù sì wí fún àwọn Olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”

5. Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Jùdéà, ó bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí ó fi dé ìhínyìí!”

6. Nígbà tí Pílátù gbọ́ orúkọ Gálílì, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Gálílì.

7. Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ Hẹ́rọ́dù ni, ó rán an sí Hẹ́rọ́dù, ẹni tí òun tìkárarẹ̀ wà ní Jerúsálémù ní àkókò náà.

8. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù, sì rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ ó sáà ti ń gbọ́ ìhìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.

9. Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá.

10. Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fí ẹ̀sùn kàn án gidigidi.

11. Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pílátù lọ.

12. Pílátù àti Hẹ́rọdù di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ijọ́ náà: nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.

13. Pílátù sì pe àwọn olórí àlúfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ.

14. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsí i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn.

15. Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsí i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.

16. Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”

17. (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)

18. Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa!”

19. Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.

20. Pílátù sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jésù sílẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélèbú, kàn án mọ àgbélèbú!”

22. Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”

23. Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélèbú, Ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.

24. Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.

25. Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

Wọ́n Kan Jésù Mọ́ Àgbélèbú

26. Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù.

27. Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún

28. Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.

29. Nítorí kíyèsí i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fúnni mu rí!’

30. Nígbà náà ni“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kékèké pé,“Bò wá mọ́lẹ̀!” ’

31. Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kínni a ó ṣe sára gbígbẹ?”

32. Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.

33. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélèbú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì.

34. Jésù sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.

35. Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

36. Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.

37. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38. Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù: ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

39. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là.”

40. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

41. Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42. Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”

43. Jésù sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!”

Ikú Jésù

44. Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.

45. Òòrùn sì ṣóòkùn, aṣọ ìkéle ti tẹ́ḿpílì sì ya ní àárin méjì,

46. Nígbà tí Jésù sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

47. Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!”

48. Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé.

49. Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gálílì wá, wọ́n dúró lókèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.

Ìsìnkú Jésù

50. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jóṣẹ́fù, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatíyà. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòótọ́.

51. Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.

52. Ọkùnrin yìí tọ Pílátù lọ, ó sì tọrọ òkú Jésù.

53. Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.

54. Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.

55. Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Gálílì wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsí ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.

56. Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.