orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àjíǹde Náà

1. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú lọ́fíńdà ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá.

2. Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì.

3. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jésù Olúwa.

4. Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n:

5. Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn ańgẹ́lì náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrin àwọn òkú?

6. Kò sí níhínyìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì.

7. Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.’ ”

8. Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9. Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.

10. Màríà Magaléènì, àti Jóánnà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn àpósítélì.

11. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.

12. Nígbà náà ni Pétérù dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrarawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

Ní Oju Ọ̀nà Sí Èmáúsì.

13. Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.

14. Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.

15. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.

16. Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

17. Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.

18. Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

19. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jésù ti Násárẹ́tì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,

20. Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú.

21. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀.

22. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì:

23. Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè.

24. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni wọn kò rí.”

25. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:

26. Kò ha yẹ kí Kírísítì ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”

27. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

28. Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú.

29. Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.

30. Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún wọn.

31. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú

32. Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”

33. Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,

34. Èmí wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì!”

35. Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.

Jésù Fi Ara Han Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Rẹ̀.

36. Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jésù tìkararẹ̀ dúró láàrin wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlààáfíà fún yín.”

37. Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.

38. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?

39. Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

40. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.

41. Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”

42. Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.

43. Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.

44. Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mósè, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Sáàmù, nípasẹ̀ mi.”

45. Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.

46. Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kírísítì jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ijọ́ kẹ́ta kúrò nínú òkú:

47. Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálémù lọ.

48. Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.

49. Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”

Ìgòkè Re Ọ̀run.

50. Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.

51. Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.

52. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerúsálémù pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀:

53. Wọ́n sì wà ní tẹ́ḿpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run. Àmín.