orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Òwe Ìforítì Opò

1. Ó sì pa òwe kan fún wọn nítorí èyí yìí pé, ó yẹ kí a má a gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀;

2. Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúṣàáájú ènìyàn.

3. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀ta mi!’

4. “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúṣàájú ènìyàn,

5. Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má baà fi wíwá rẹ̀ nígbákùúgbà dá mi lágara.’ ”

6. Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!

7. Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?

8. Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”

Òwe Farisí Àti Agbowó Òde

9. Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn;

10. Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹ́ḿpílì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.

11. Èyí Farisí dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

12. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́ṣẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

13. “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’

14. “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”

Àwọn Ọmọdé Àti Jésù

15. Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè fi ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí.

16. Ṣùgbọ̀n Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.

17. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”

Ọlọ́rọ̀ Alákòso

18. Ìjòyè kan sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kínni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

19. Jésù wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.

20. Ìwọ mọ̀ àwọn òfin, ‘Má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe pànìyàn, má ṣe jalè, má ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ.’ ”

21. Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”

22. Nígbà tí Jésù sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn talákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra lọ́run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23. Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

24. Nígbà tí Jésù rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!

25. Nítorí ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”

26. Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ tani ó ha lè là?”

27. Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

28. Pétérù sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa silẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”

29. Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run,

30. Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

Jésù Tún Sọ Nípa Ikú Rẹ̀

31. Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn.

32. Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ si i lára.

33. Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ijọ́ kẹ́ta yóò sì jíǹde.”

34. Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn: ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.

Afọ́jú Alágbe Gba Ìwòsàn

35. Bí ó ti súnmọ́ Jẹ́ríkò, afọ́jú kan jókòó lẹ́bá ọ̀nà ó ń ṣagbe:

36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó bèèrè pé, kíni a lè mọ èyí sí.

37. Wọ́n sì wí fún un pé, “Jésù ti Násárẹ́tì ni ó ń kọjá lọ.”

38. Ó sì kígbe pé, “Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

39. Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

40. Jésù sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í,

41. Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

42. Jésù sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

43. Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.