orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Wọ́n Bèèrè Nípa Àṣẹ Jésù

1. Ní ijọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́ḿpìlì tí ó sì ń wàásù ìyìn rere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn alàgbà dìde sí i.

2. Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe ǹkan wọ̀nyí? Tàbí tani ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”

3. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.

4. Bamitísímù ti Jòhánù, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”

5. Wọ́n sì bá ara wọn gbérò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun ó wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

6. Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Jòhánù.”

7. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Wọn kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”

8. Jésù sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

Òwe Àwọn Ayálégbé

9. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.

10. Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

11. Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

12. Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta: wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

13. “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un.’

14. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbérò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tìí jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.“Ǹjẹ́ kínni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?

16. Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri I!”

17. Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,Òun náà ni ó di pàtàkì igun kilé’?

18. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá subú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

19. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

Sísan Owó Orí Fún Késárì

20. Wọ́n sì ń sọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn amí tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtọ́ ènìyàn, kí wọn baà lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn baà lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

21. Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣojúsájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lótítọ́.

22. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”

23. Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

24. “Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀?”

25. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Késárì ni.”Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

26. Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

Àjíǹde Àti Ìgbéyàwó

27. Àwọn Ṣadusí kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í,

28. Wí pé, “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.

29. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.

30. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.

31. Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.

32. Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.

33. Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya tìtani yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sáà ni ín ní aya.”

34. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni.

35. Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni.

36. Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn áńgẹ́lì dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.

37. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mósè tìkararẹ̀ sì ti fihàn ní ìgbẹ́, nígbà tí ó pe Olúwa ni Ọlọ́run Ábúráhámù, àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.

38. Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un.”

39. Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”

40. Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.

Ọmọ Tan Ni Jésù Ń Se

41. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dáfídì ni Kírísítì?

42. Dáfídì tìkárarẹ̀ sì wí nínú ìwé Psalmu pé:“ ‘JÈHÓFÀ wí fún Olúwa mi pé:“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

43. Títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

44. Ǹjẹ́ bí Dáfídì bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

45. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé,

46. “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn ní aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú sínágọ́gù, àti ipò ọlá ní ibi àsè;

47. Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”