orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì

1. A sì fi ìféèfé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹ́ḿpílì Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.

2. Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì.

3. Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ̀rìí mi méjèèje, wọn o sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fa ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ-ọ̀fọ̀.”

4. Wọ̀nyí ni igi olífì méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lara, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀ta wọn run: bayìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.

6. Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-àrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.

7. Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.

8. Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sódómù àti Éjíbítì nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.

9. Fún ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì.

10. Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró,

11. Àti lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí iyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹṣẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.

12. Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkúukúù àwọsánmà; lójú àwọn ọ̀ta wọn.

13. Ní wákàtí náà ìmìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ̀wàá ìlú náà sì wó, àti nínú ìmìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.

14. Ègbé kéjì kọjá; sì kìyèsí i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.

Ìpè Méje

15. Ańgẹ́lì kéje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kírísítì rẹ̀;òun yóò sì jọba láé àti láéláé!”

16. Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run,

17. Wí pé:“Àwa fí ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,ìwọ sì ti jọba.

18. Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ni ìbínú rẹ̀ ti dé,àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”

19. A sì ṣí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mu nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ́ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.