orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Halelúyà

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:“Halelúyà!Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá agbára,

2. nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

3. Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:“Halelúyà!Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

4. Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:“Àmín, Halelúyà!”

5. Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti èwe àti àgbà!”

6. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:“Halelúyà!Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.

7. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,kí a sì fi ògo fún un.Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,aya rẹ̀ sì ti múra tán.

8. Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9. Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10. Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni Tó Gun Ẹsin Funfun

11. Mo sì rí ọ̀run sí sílẹ̀, sì wò ó, ẹsin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòótọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun.

12. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkárarẹ̀.

13. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

14. Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọrùn tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn lórí ẹ̀sin funfun.

15. Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn:” ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.

16. Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:ỌBA ÀWỌN ỌBA ÀTI Olúwa ÀWỌN Olúwa

17. Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run;

18. Kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹsin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrù, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19. Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbájọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà àti ogun rẹ̀ jagun.

20. A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèje yìí ni a sọ láàyè sínú adágún iná tí ń fi súfúrù jó.

21. Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹsin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran ara wọn yó.