orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìtẹ́ Ọ̀run

1. Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsí i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ̀yìn èyí hàn ọ́.”

2. Lójú kan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsí i, a tẹ́ ìtẹ́ kan lọ́run ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà.

3. Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jásípérì àti sádíúsì lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta émérádì lójú.

4. Yíká ìtẹ́ náà sì ni ìtẹ́ mẹ́rínlélógún; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn.

5. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.

6. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi digi wà tí o dàbí Kírísítálì: Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ̀yìn wà.

7. Ẹ̀dá kínní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kéjì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹ́rin sì dàbí ìdì tí ń fò.

8. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé:“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́,Olúwa Ọlọ́run Olódùmare,tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

9. Nígbà tí àwọn ẹ̀dá aláàyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láàyè láé àti láéláé.

10. Àwọn àgbà mẹ́rinlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

11. “Olúwa, ìwọ ni o yẹláti gba ògo àti ọlá àti agbára:nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ niwọn fi wà tí a sì dá wọn.”