orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ańgẹ́lì Àti Ìwé Kékeré

1. Mó sì rí ańgẹ́lì mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi awọsànmà wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná.

2. Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a sí ní owọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹṣẹ rẹ̀ ọ̀tún lé òkun, àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀.

3. Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.

4. Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”

5. Ańgẹ́lì náà tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run:

6. Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láé láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, pé, “Kí a má ṣe jáfara mọ́.

7. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn ìpè ańgẹ́lì kéje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”

8. Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí a ṣí náà lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí o dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀.”

9. Mo sì tọ ańgẹ́lì náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.? Ó sì wí fún mi pé, ‘Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.’ ”

10. Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ ańgẹ́lì náà mo sì jẹ ẹ́ tan; ó sì dùn lẹ́nù mi bí oyin; bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò.

11. A sì wí fún mi pé, “Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba.”