orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọ̀rọ̀ Ìsáájú

1. Ìfihàn ti Jésù Kírísítì, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi hàn fún àwọn ìranṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìsẹ ní lọ́ọ́lọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ ańgẹ́lì rẹ̀ wá fún Jòhánù, ìránṣẹ́ rẹ̀:

2. Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jésù Kírísítì.

3. Olúkúlùkù ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ̀lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọ́n-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìkíni Àti Ìyìn

4. Jòhánù,Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà:Ore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;

5. Àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, ẹlẹ́rì olóòótọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,

6. Tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.

7. Kíyèsí i, Ó ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;gbogbo ojú ni yóò sì rí i,àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ náà ni. Àmín.

8. “Èmi ni Álfà àti Òmégà,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, Olódùmarè.”

Ọ̀kan Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ènìyàn

9. Èmi, Jòhánù, arákùnrin yín àti alábàápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jésù, wà ní erekùsù tí a ń pè ní Patimo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jésù Kírísítì.

10. Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ̀yìn mi, bí ìró ipè,

11. Ó ń wí pé, “Èyí tí ó wí pé, kọ̀wé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Éfésù, àti sí Simirínà, àti sí Párágámù, àti sí Tíátírà, àti sí Sarádì, àti sí Filadéfíà, àti sí Laódíkéà.”

12. Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje;

13. Àti láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dà bí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹṣẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́.

14. Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí Sínóò; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná;

15. Ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀.

16. Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí òòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

17. Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó si fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Máṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni-ìṣájú àti ẹni-ìkẹyìn.

18. Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsí i, èmi sì ń bẹ láàyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò-òkú.

19. “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí;

20. Ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn ańgẹ́lì ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.