Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Pọ́ọ̀lù má baà di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrin wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.