orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hósíà ọmọ Béérì wá ní àkókò ìjọba Ùsáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà; àwọn ọba Júdà àti ní àkókò ọba Jéróbóámù ọmọ Jóásì ní Ísírẹ́lì:

Ìdílé Hósíà

2. Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hósíà, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún araa rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.”

3. Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gómérì ọmọbìnrin Díbíláémù, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.

4. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hósíà pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jésírẹ́lì, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jéhù ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jésírẹ́lì, Èmi yóò sì mú ìjọba Ísírẹ́lì wá sí òpin.

5. Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò sẹ́ ọrun Ísírẹ́lì ní àfonífojì Jésírẹ́lì.”

6. Gómérì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Ísírẹ́lì mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n.

7. Síbẹ̀, èmi yóò ṣàáànú fún ilé Júdà, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”

8. Lẹ́yìn ìgbà tí ó (gba ọmú lẹ́nu rẹ̀) Lo-rúhámà, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni

9. Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ámì, (kì í ṣe ènìyàn mi) nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

10. “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò pọ̀ bíi iyanrìn etí òkun tí a kò le wọ̀n, tí a kò sì le è kà, yóò síṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’

11. Àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yóò para pọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jésírẹ́lì yóò jẹ́.