orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

A Mú Ísírẹ́lì Padà Bọ́ Sípò

1. Yípadà ìwọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!

2. Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,Kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.Ẹ sọ fún un pé:“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wákí o sì fi oore ọ̀fẹ́ gbà wá,kí àwa kí ó lè fí ètè wa sán-an fún ọ

3. Asíríà kò le gbà wá là;A kò ní í gorí ẹsin ogunA kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé‘Àwọn ni òrìṣà wasí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọnaláìní baba tí ń rí àánú.’

4. “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ wọn.

5. Èmi o dàbí ìrì sí Ísírẹ́lìwọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílìyóò sì ta gbòngbòkédárì ti Lébánónì

6. Àsẹ̀sẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,Didan ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi ólífìÒórùn rẹ yóò sì dàbí igi sídà ti Lébánónì.

7. Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.Yóò rúwé bi ọkà.Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lébánónì.

8. Ìwọ Éfúráímù; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?Èmi ó daba! lóhùn, èmi o sì ṣe ìtọ́jú rẹ.Mo dàbí igi tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

9. Ta ni ọlọgbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyíTa a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.Tí tọ́ ni ọ̀nà Olúwaàwọn olódodo si ń rìn nínú wọnṢùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ nìyóò kọsẹ̀ nínú wọn.