orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìdájọ́ Fún Ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì

1. Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì;má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀ èdè yòókù.Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìsòótọ́ si lọ́run yín.Ẹ fẹ́ràn láti gbowó iṣẹ́ àgbèrèní gbogbo ilẹ̀ ìpàkà.

2. Àwọn ilé ìpàkà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹwáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀

3. Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé OlúwaÉfúráímù yóò padà sí ÉjíbítìYóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ̀ ní Ásíríà.

4. Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọnkò ńi wá sí orí tẹ́ḿpìlì Olúwa

5. Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àsè yín tí a ti yànní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?

6. Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparunÉjíbítì yóò kó wọn jọ,Mémúfísì yóò sì sin wọ́n.Ibi ìsọjọ̀ sílífa wọn ni yèrèpè yóò jogún,Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.Ẹ̀gún yóò sì bogbogbo àgọ́ wọn.

7. Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;Àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti déJẹ́ kí Ísírẹ́lì mọ èyíNítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀A ka ẹni ìmísí sí asínwín.

8. Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,ni olùṣọ́ ọ Éfúráímù.Ṣíbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀

9. Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ GíbíàỌlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọnyóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

10. “Nígbà tí mo rí Ísírẹ́lì,Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí èso àjàrà ní ilẹ̀ aṣálẹ̀Nígbà tí mo rí àwọn baba yín.Ó dàbí ìgbà tí ènìyàn rí àkọ́so èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Baali-PéórìWọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá niwọ́n di aláìmọ́ bí ohun tí wọ́n fẹ́ràn.

11. Ògo Éfúráímù yóò fò lọ bí ẹyẹkò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.

12. Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọnÈgbé ni fún wọn,nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!

13. Mo rí Éfúráímù bí ìlú Tírúsìtí a tẹ̀dó sí ibi dáradáraṣùgbọ́n Éfúráímù yóò kó àwọnọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”

14. Fún wọn, Olúwa!Kí ni ìwọ yóò fún wọn?Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́àti ọyàn gbígbẹ.

15. “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní GílígálìMo kórìírà wọn níbẹ̀,Nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé miÈmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.

16. Éfúráímù ti rẹ̀ dànùGbogbo rẹ̀ sì ti rọ,kò sì so èso,Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

17. Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀nítorí pé wọn kò gbọ́ràn sí i;wọn yóò sì di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.