orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìfẹ́ Ọlọ́run Sí Ísírẹ́lì

1. “Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,mo sì pe ọmọ mi jáde wá láti Éjíbítì.

2. Wọ́n rúbọ sí Báálì bí mo ṣe ń pe Ísírẹ́lì síbẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀mi jìnnà sí i: wọn rúbọ sí báálímu,wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.

3. Lóòtọ́ mo kọ́ Éfúráímù pẹ̀lú ní ìrìnmo di wọ́n mú ní apá,ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀pé mo ti mú wọn lára dá.

4. Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́nàti ìdè ìfẹ́.Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọnMo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.

5. “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bíṢé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bínítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?

6. Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọnyóò si bá gbogbo irin ẹnú odi ìlú wọn jẹ́yóò sì fòpin sí gbogbo èrò wọn.

7. Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ miBí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ ọ̀gá-ògo júlọ,kò ní gbé wọn ga rárá.

8. “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù?Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lìBáwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà?Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù?Ọkàn mi yípadà nínú miÀánú mi sì ru sókè

9. Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹtàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoroNítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyànẸni mímọ́ láàrin yín,Èmi kò ni i wa nínú ìbínú

10. Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìúnNígbà tó bá búàwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn.

11. Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rùbi i ẹyẹ láti Éjíbítìbi i àdàbà láti ÁsíríàÈmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”ni Olúwa wí.

Ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì.

12. Éfúráímù tí fi irọ́ yí mi káilé Ísírẹ́lì pẹ̀lú ẹ̀tàn.Ṣùgbọ́n Júdà sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́runÓ sì ṣe olóòótọ́ sí Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.