orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àlàáfíà lẹ́yìn ìyípadà Ní Ọlọ́run.

1. Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ ṣíwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,

2. àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí.

3. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè níbi tí ó ti fọ́n ọn yín ká sí.

4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà.

5. Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ síi ju àwọn baba yín lọ.

6. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ.

7. Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ẹkún un yín wá sórí àwọn ọ̀ta à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni ì rẹ.

8. Ìwọ yóò tún gbọ́ràn sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí.

9. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú ù rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èṣo ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú ù rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.

10. Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.

Ìfifún Ìyè Tàbí Ikú.

11. Wàyí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un yín lónìí kò le jù fún un yín tàbí kọjá agbára yín.

12. Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?”

13. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?”

14. Kìí ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí ì rẹ, ó wà ní ẹnu ù rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.

15. Wòó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun.

16. Nítorí mo pàṣẹ fún ọ lónìí láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti rìn ní ọ̀nà a rẹ̀ àti láti pa àwọn àṣẹ, ìpinnu àti òfin rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò máa gbé tí o ó sì máa pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún ọ ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

17. Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n,

18. èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní-àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jọ́dánì láti gbà àti láti ní.

19. Lónìí mo pe ọ̀run àti ayé bí ẹlẹ́rìí sí ọ pé mo ti gbékalẹ̀ síwájú rẹ ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún. Nísinsìnyìí yan ìyè, nítorí kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè gbé

20. kí ìwọ sì lè fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetí sílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.