orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ikú Mósè.

1. Nígbà náà ni Móṣè gun òkè Nébò láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù sí orí Písigà tí ó dojú kọ Jẹ́ríkò. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gílíádì dé Dánì,

2. gbogbo Náfítanì, ilẹ̀ Éfúrámù àti Mánásè, gbogbo ilẹ̀ Júdà títí dé òkun ìwọ̀-oòrùn.

3. Gúṣù àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ dé Sóárì.

4. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò débẹ̀.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni Mósè ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Móábù, bí Olúwa ti wí.

6. Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù, tí ó kọjú sí Béhì-Péórì, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnì kan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà.

7. Mósè jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.

8. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣunkún un Móṣè ní pẹ̀tẹ́lẹ́ Móábù ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Móṣè parí.

9. Jóṣúà ọmọ Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Móṣè ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lée lórí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún Mósè.

10. Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Ísírẹ́lì bí i Móṣè, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú,

11. tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.

12. Nítorí kò sí ẹni tí ó tíì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Móṣè fi hàn ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì.