orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Òfin Mẹ́wàá

1. Mósè sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì wí pé: Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etíìgbọ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.

2. Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Hórébù.

3. Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí.

4. Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrin iná lórí òkè.

5. (Ní ìgbà yìí, mo wà láàrin ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè) Ó sì wí pé:

6. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Íjíbitì láti oko ẹrú wá.

7. “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú ù mi.

8. “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín ní ìrí ohunkóhun lọ́run tàbí ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn-ín tàbí nínú omi ní ìṣàlẹ̀.

9. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ láti sìn wọ́n. Torí pé èmi Olúwa Ọlọ́run yín Ọlọ́run owú ni mí, tí í fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹ́ta àti ẹ̀kẹ́rin ní ti àwọn tí ó kórìíra mi.

10. Ṣùgbọ́n mo ń fí ìfẹ́ han ẹgbẹẹgbẹ̀rùn-ún ìran àwọn tí ó fẹ́ràn mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́.

11. “Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.

12. “Ẹ kíyèsí ọjọ́ ìsinmi láti pa á mọ́ bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.

13. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, kí ẹ ṣe iṣẹ́ ẹ yín pátapáta

14. Ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje ni ọjọ́ ìsinmi sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà yálà ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí àwọn ọmọ rẹ obìnrin, tàbí àwọn ẹrú ọkùnrin tàbí ẹrú obìnrin yín tàbí màlúù yín, tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹran yín, tàbí àwọn àlejò yín, kí àwọn ẹrú-kùnrin àti ẹrú-bìnrin yín le è sinmi, bí i yín.

15. Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, àti pé Olúwa Ọlọ́run yín yọ yín kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín ṣe pàṣẹ fún un yín láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.

16. “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyáà rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ ba à le è pẹ́ láyé, àti kí ó bá à lè dára fún un yín ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín.

17. “Má ṣe pànìyàn.

18. “Má ṣe ṣe panṣágà.

19. “Má ṣe jalè.

20. “Má ṣe jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ

21. “Má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí aya aládúgbò rẹ, má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí ilé tàbí ilẹ̀ alábágbé rẹ, sí ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí ohunkóhun tí í ṣe ti aládúgbò rẹ.”

22. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri: Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.

23. Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn alàgbà a yín tọ̀ mí wá.

24. Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárin iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láàyè lẹ́yìn tí Olúwa bá bá a sọ̀rọ̀.

25. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.

26. Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?

27. Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́ran.”

28. Ọlọ́run ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀ Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,

29. ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.

30. “Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn.

31. Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àsẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”

32. Torí èyí ẹ sọ́ra láti máa ṣe ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí sósì.

33. Ẹ rìn ní gbogbo ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín, kí ẹ bá à le yè, kí ó sì dára fún un yín, kí ọjọ́ ọ yín bá à lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò gbà.