orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ ènìyàn wá.

2. Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.

3. Kí Ámónì tàbí Móábù tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹ̀wàá.

4. Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Éjíbítì àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégún Bálámù ọmọ Béórì ará a Pétórì ti Árámù Náháráímù.

5. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Bálámù ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.

6. Má ṣe wá ìpinnu ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú u wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láàyè.

7. Má ṣe kórìíra ará Édómù kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Má se kórìíra ará Éjíbítì, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àléjò ní ilẹ̀ rẹ̀.

8. Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

Ìwà àìmọ́ nínú àgọ́:

9. Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.

10. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

12. Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.

13. Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.

14. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín.

Onírúurú òfin:

15. Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

16. Jẹ́ kí ó máa gbé láàrin rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyí ìlú tí ó bá mú. Má se ni í lára.

17. Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Ísírẹ́lì má ṣe padà di alágbérè ojúbọ òrìṣà.

18. O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì.

19. Má ṣe ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.

20. O lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

21. Bí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ọ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.

22. Ṣùgbọ́n tí o bá fà ṣẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi.

23. Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá sọ jáde láti ẹnu rẹ, nítorí pé o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.

24. Bí o bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi ìkankan sínú agbọ̀n rẹ.

25. Bí o bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya sírì rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.