Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 7:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún àkọ́kọ́ Beliṣáṣárì ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe ṣùn sórí ibùṣùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.

2. Dáníẹ́lì sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi òkun ńlá sókè.

3. Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú òkun náà.

4. “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́-apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́-apá rẹ̀ naa tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

5. “Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; bíárì. Ó gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrin ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’

6. “Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.

7. “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi lóru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rù ba ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin títóbi; ó ń rùn, ó sì ń pa ohun alààyè tí ó ṣẹ́ kù jẹ, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.

8. “Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárin wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fà tu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

9. “Bí mo ṣe ń wò,“a gbé ìtẹ́ ọba sí ìkàlẹ̀ẹni ìgbàanì orí ìtẹ́ rẹ̀Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwúIrun orí i rẹ̀ funfun bí òwúÌtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

10. Odò iná ń ṣànó ń jáde ní iwájú u rẹ̀Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́ná ẹgbẹ̀rún ń foríbalẹ̀ fún un;Ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rúnmẹ́wàá sì dúró níwájú u rẹ̀.Àwọn onídàájọ́ jókòóa sì sí àwọn ìwé sílẹ̀.

11. “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.

12. A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yóòkù, ṣùgbọ́n a fún wọn láàyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 7