orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Olúwa Yóò Gba Júdà

1. Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,fún olúkúlúkù koríko ní pápá.

2. Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,wọn sì tí rọ àlá èké;wọ́n ń tu ni nínú láṣán,nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí.

3. “Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,èmi o sì jẹ àwọn olórí níyànítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,ilé Júdà wò,yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.

4. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni igi-èèkàn àgọ́ tí wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.

5. Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrinalágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.”

6. “Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára,èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là,èmi ó sì tún mú wọn padànítorí mo tí ṣàánú fún wọn,ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù;nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,èmi o sì gbọ́ ti wọn

7. Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára,ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì:àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.

8. Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ;nítorí èmi tí rà wọ́n padà;wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bíwọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè:ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn;wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,wọn ó sì tún padà.

10. Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítìpẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà:èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì; aa kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ.

11. Wọn yóò sì la òkun wàhálà já,yóò sì lu rírú omi nínú òkun,gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀,ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò.

12. Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”ni Olúwa wí.