orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Òdodo Àti Àánú, Kì í Ṣe Ààwẹ̀

1. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dáríúsì ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekaráyà wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kísíléfì tí ń se oṣù kẹsàn-án.

2. Nígbà tí wọ́n rán Sérésérì àti Régémélékì, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojú rere Olúwa.

3. Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù kárùnún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”

4. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé,

5. “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùnún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin hà ń gbààwẹ̀ yín fún?

6. Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí?

7. Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọdọ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jérúsálẹ́mù, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekaráyà wá, wí pé:

9. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti iyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀.

10. Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tàlákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbérò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’

11. “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́.

12. Wọ́n sé àyà wọn bí òkúta ádámáńtì, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá: ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ ogun wá.

13. “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

14. ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dáhoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjà tàbí kí ó padà bọ̀: wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dáhoro.’ ”