orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìwé-Kíkà Ti Ń Fò.

1. Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, ìwé-kíkà ti ń fò.

2. Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé-kíkà tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”

3. Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó gèé kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀.

4. ‘Èmi o mú un jáde,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi ọrúkọ mi búra èké: yóò si wà ni àárin ilé rẹ̀, yóò si rún un pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”

Obìnrin Nínú Agbọ̀n

5. Ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wo nǹkan yìí tí ó jáde lọ.”

6. Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n éfà tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”

7. Sì kíyèsí i, a gbé talẹ́ńtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárin òṣùwọ̀n éfà.

8. Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà-búburú.” Ó sì jù ú sí àárin òṣùwọ̀n éfà: ó sì ju òṣùwọ̀n òjé sí ẹnu rẹ̀.

9. Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsí i, obìnrin méjì jáde wá, èfúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n éfà náà dé àárin méjì ayé àti ọ̀run.

10. Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n éfà náà lọ.”

11. Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀ èdè Bábílónì láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣe tán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”